15. Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho aya ọmọ rẹ: nitoripe aya ọmọ rẹ ni iṣe; iwọ kò gbọdọ tú ìhoho rẹ̀.
16. Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho aya arakunrin rẹ: ìhoho arakunrin rẹ ni.
17. Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho obinrin ati ti ọmọbinrin rẹ̀; bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ fẹ ọmọbinrin ọmọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọbinrin ọmọ rẹ̀ obinrin, lati tú ìhoho wọn; nitoripe ibatan ni nwọn: ohun buburu ni.
18. Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ fẹ́ arabinrin aya rẹ li aya, lati bà a ninu jẹ́, lati tú ìhoho rẹ̀, pẹlu rẹ̀ nigbati o wà lãye.
19. Ati pẹlu iwọ kò gbọdọ sunmọ obinrin kan lati tú u ni ìhoho, ni ìwọn igbati a yà a sapakan nitori aimọ́ rẹ̀.
20. Pẹlupẹlu iwọ kò gbọdọ bá aya ẹnikeji rẹ dàpọ lati bà ara rẹ jẹ́ pẹlu rẹ̀.
21. Iwọ kò si gbọdọ fi irú-ọmọ rẹ kan fun Moleki, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bà orukọ Ọlọrun rẹ jẹ́: Emi li OLUWA.
22. Iwọ kò gbọdọ bá ọkunrin dápọ bi obinrin: irira ni.
23. Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bá ẹranko kan dàpọ, lati fi i bà ara rẹ jẹ́: bẹ̃ni obinrin kan kò gbọdọ duro niwaju ẹranko kan lati dubulẹ tì i: idaru-dàpọ ni.
24. Ẹ máṣe bà ara nyin jẹ́ ninu gbogbo nkan wọnyi: nitoripe ninu gbogbo nkan wọnyi li awọn orilẹ-ède, ti mo lé jade niwaju nyin dibajẹ́:
25. Ilẹ na si dibajẹ́: nitorina ni mo ṣe bẹ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ wò lori rẹ̀, ilẹ tikararẹ̀ si bì awọn olugbé rẹ̀ jade.
26. Nitorina ni ki ẹnyin ki o ṣe ma pa ìlana ati ofin mi mọ́, ki ẹnyin ki o máṣe ṣe ọkan ninu irira wọnyi; tabi ẹnikan ninu ibilẹ nyin, tabi alejò ti nṣe atipo ninu nyin:
27. Nitoripe gbogbo irira wọnyi li awọn ọkunrin ilẹ na ṣe, ti o ti wà ṣaju nyin, ilẹ na si dibajẹ́;
28. Ki ilẹ na ki o má ba bì nyin jade pẹlu, nigbati ẹnyin ba bà a jẹ́, bi o ti bì awọn orilẹ-ède jade, ti o ti wà ṣaju nyin.
29. Nitoripe ẹnikẹni ti o ba ṣe ọkan ninu irira wọnyi, ani ọkàn wọnni ti o ba ṣe wọn li a o ke kuro lãrin awọn enia wọn.
30. Nitorina ni ki ẹnyin ki o pa aṣẹ mi mọ́, ki ẹnyin ki o máṣe ọkan ninu irira wọnyi, ti nwọn ti ṣe ṣaju nyin, ki ẹnyin ki o má si bà ara nyin jẹ́ ninu rẹ̀: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.