Lef 18:10-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Ìhoho ọmọbinrin ọmọ rẹ ọkunrin, tabi ti ọmọbinrin ọmọ rẹ obinrin, ani ìhoho wọn ni iwọ kò gbọdọ tú: nitoripe ìhoho ara rẹ ni nwọn.

11. Ìhoho ọmọbinrin aya baba rẹ, ti a bi lati inu baba rẹ wá, arabinrin rẹ ni, iwọ kò gbọdọ tú ìhoho rẹ̀.

12. Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho arabinrin baba rẹ: ibatan baba rẹ ni.

13. Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho arabinrin iya rẹ: nitoripe ibatan iya rẹ ni.

14. Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho arakunrin baba rẹ, iwọ kò gbọdọ sunmọ aya rẹ̀: arabinrin baba rẹ ni.

15. Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho aya ọmọ rẹ: nitoripe aya ọmọ rẹ ni iṣe; iwọ kò gbọdọ tú ìhoho rẹ̀.

16. Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho aya arakunrin rẹ: ìhoho arakunrin rẹ ni.

17. Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho obinrin ati ti ọmọbinrin rẹ̀; bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ fẹ ọmọbinrin ọmọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọbinrin ọmọ rẹ̀ obinrin, lati tú ìhoho wọn; nitoripe ibatan ni nwọn: ohun buburu ni.

18. Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ fẹ́ arabinrin aya rẹ li aya, lati bà a ninu jẹ́, lati tú ìhoho rẹ̀, pẹlu rẹ̀ nigbati o wà lãye.

19. Ati pẹlu iwọ kò gbọdọ sunmọ obinrin kan lati tú u ni ìhoho, ni ìwọn igbati a yà a sapakan nitori aimọ́ rẹ̀.

20. Pẹlupẹlu iwọ kò gbọdọ bá aya ẹnikeji rẹ dàpọ lati bà ara rẹ jẹ́ pẹlu rẹ̀.

21. Iwọ kò si gbọdọ fi irú-ọmọ rẹ kan fun Moleki, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bà orukọ Ọlọrun rẹ jẹ́: Emi li OLUWA.

22. Iwọ kò gbọdọ bá ọkunrin dápọ bi obinrin: irira ni.

23. Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bá ẹranko kan dàpọ, lati fi i bà ara rẹ jẹ́: bẹ̃ni obinrin kan kò gbọdọ duro niwaju ẹranko kan lati dubulẹ tì i: idaru-dàpọ ni.

24. Ẹ máṣe bà ara nyin jẹ́ ninu gbogbo nkan wọnyi: nitoripe ninu gbogbo nkan wọnyi li awọn orilẹ-ède, ti mo lé jade niwaju nyin dibajẹ́:

Lef 18