10. Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba si ṣe ti agbo-ẹran, eyinì ni ti agutan, tabi ti ewurẹ, fun ẹbọ sisun; akọ ni ki o múwa alailabùku.
11. Ki o si pa a niwaju OLUWA li ẹba pẹpẹ ni ìha ariwa: ati awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni yio si bù ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n ori pẹpẹ na yiká.
12. Ki o si kun u, ori rẹ̀ ati ọrá rẹ̀: alufa na yio si tò wọn sori igi ti mbẹ lori iná ti mbẹ lori pẹpẹ:
13. Ṣugbọn ki o ṣìn ifun ati itan rẹ̀ ninu omi: ki alufa na ki o si mú gbogbo rẹ̀ wá, ki o si sun u lori pẹpẹ: ẹbọ sisun ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.