51. Bi o si ti nsọkalẹ lọ, awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pade rẹ̀, nwọn si wi fun u pe, ọmọ rẹ yè.
52. Nigbana li o bère wakati ti o bẹ̀rẹ si isàn lọwọ wọn. Nwọn si wi fun u pe, Li ana, ni wakati keje, ni ibà na fi i silẹ.
53. Bẹ̃ni baba na mọ̀ pe, ni wakati kanna ni, ninu eyi ti Jesu wi fun u pe, Ọmọ rẹ yè: on tikararẹ̀ si gbagbọ́, ati gbogbo ile rẹ̀.
54. Eyi ni iṣẹ́ ami keji, ti Jesu ṣe nigbati o ti Judea jade wá si Galili.