20. Nigbati o si ti wi bẹ̃ tan, o fi ọwọ́ ati ìha rẹ̀ hàn wọn. Nitorina li awọn ọmọ-ẹhin yọ̀, nigbati nwọn ri Oluwa.
21. Nitorina Jesu si tún wi fun wọn pe, Alafia fun nyin: gẹgẹ bi Baba ti rán mi, bẹ̃li emi si rán nyin.
22. Nigbati o si ti wi eyi tan, o mí si wọn, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbà Ẹmí Mimọ́:
23. Ẹṣẹ ẹnikẹni ti ẹnyin ba fi jì, a fi ji wọn; ẹ̀ṣẹ ẹnikẹni ti ẹnyin ba da duro, a da wọn duro.
24. Ṣugbọn Tomasi, ọkan ninu awọn mejila, ti a npè ni Didimu, kò wà pẹlu wọn nigbati Jesu de.
25. Nitorina awọn ọmọ-ẹhin iyokù wi fun u pe, Awa ti ri Oluwa. Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Bikoṣepe mo ba ri àpá iṣo li ọwọ́ rẹ̀ ki emi ki o si fi ika mi si àpá iṣó na, ki emi ki o si fi ọwọ́ mi si ìha rẹ̀, emi kì yio gbagbó.