Joh 1:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI àtetekọṣe li Ọ̀rọ wà, Ọ̀rọ si wà pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun si li Ọ̀rọ na.

2. On na li o wà li àtetekọṣe pẹlu Ọlọrun.

3. Nipasẹ̀ rẹ̀ li a ti da ohun gbogbo; lẹhin rẹ̀ a ko si da ohun kan ninu ohun ti a da.

4. Ninu rẹ̀ ni ìye wà; ìye na si ni imọlẹ̀ araiye.

5. Imọlẹ na si nmọlẹ ninu òkunkun; òkunkun na kò si bori rẹ̀.

6. Ọkunrin kan wà ti a rán lati ọdọ Ọlọrun wá, orukọ ẹniti njẹ Johanu.

7. On na li a si rán fun ẹri, ki o le ṣe ẹlẹri fun imọlẹ na, ki gbogbo enia ki o le gbagbọ́ nipasẹ rẹ̀.

8. On kì iṣe imọlẹ̀ na, ṣugbọn a rán a wá lati ṣe ẹlẹri fun Imọlẹ na.

9. Imọlẹ otitọ mbẹ ti ntàn mọlẹ fun olúkulùku enia ti o wá si aiye.

10. On si wà li aiye, nipasẹ rẹ̀ li a si ti da aiye, aiye kò si mọ̀ ọ.

11. O tọ̀ awọn tirẹ̀ wá, awọn ará tirẹ̀ kò si gbà a.

12. Ṣugbọn iye awọn ti o gbà a, awọn li o fi agbara fun lati di ọmọ Ọlọrun, ani awọn na ti o gbà orukọ rẹ̀ gbọ́:

Joh 1