9. Bẹ̃ni Elifasi, ara Tema, ati Bildadi, ara Ṣua, ati Sofari, ara Naama lọ, nwọn si ṣe gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun wọn: OLUWA si gbà oju Jobu.
10. OLUWA si yi igbekun Jobu pada, nigbati o gbadura fun awọn ọrẹ rẹ̀: OLUWA si busi ohun gbogbo ti Jobu ni rí ni iṣẹpo meji.
11. Nigbana ni gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo awọn arabinrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ti o ti ṣe ojulumọ rẹ̀ rí, nwọn mba a jẹun ninu ile rẹ̀, nwọn si ṣe idaro rẹ̀, nwọn si ṣipẹ fun nitori ibí gbogbo ti OLUWA ti mu ba a: olukuluku enia pẹlu si bùn u ni ike owo-kọkan ati olukuluku ni oruka wura eti kọ̃kan.
12. Bẹ̃li OLUWA bukún igbẹhin Jobu jù iṣaju rẹ̀ lọ; o si ni ẹgba-meje agutan, ẹgba-mẹta ibakasiẹ, ati ẹgbẹrun ajaga ọda-malu, ati ẹgbẹrun abo kẹtẹkẹtẹ.
13. O si ni ọmọkunrin meje ati ọmọbinrin mẹta.
14. O si sọ orukọ akọbi ni Jemima, ati orukọ ekeji ni Kesia, ati orukọ ẹkẹta ni Keren-happuki.
15. Ati ni gbogbo ilẹ na, a kò ri obinrin ti o li ẹwa bi ọmọbinrin Jobu; baba wọn si pinlẹ fun wọn ninu awọn arakunrin wọn.
16. Lẹhin eyi Jobu wà li aiye li ogoje ọdun, o si ri awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati awọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ani iran mẹrin.
17. Bẹ̃ni Jobu kú, o gbó, o si kún fun ọjọ.