7. Ipa ọ̀na na ni ẹiyẹ kò mọ̀, ati oju gunugun kò ri i ri.
8. Awọn ọmọ kiniun kò rin ibẹ rí, bẹ̃ni kiniun ti nké ramuramu kò kọja nibẹ rí.
9. O fi ọwọ rẹ̀ le akọ apata, o yi oke-nla po lati idi rẹ̀ wá.
10. O si la ipa-odò ṣiṣàn ninu apata, oju rẹ̀ si ri ohun iyebiye gbogbo.
11. O si sé iṣàn odò ki o má ṣe kún akunya, o si mu ohun ti o lumọ hàn jade wá si imọlẹ.
12. Ṣugbọn nibo li a o gbe wá ọgbọ́n ri, nibo si ni ibi oye?
13. Enia kò mọ̀ iye rẹ̀, bẹ̃li a kò le iri i ni ilẹ awọn alãyè.
14. Ọgbun wipe, kò si ninu mi, omi-okun si wipe, kò si ninu mi.
15. A kò le fi wura rà a, bẹ̃li a kò le ifi òṣuwọn wọ̀n fadaka ni iye rẹ̀.
16. A kò le fi wura Ofiri diyele e, pẹlu okuta oniksi iyebiye, ati okuta Safiri.
17. Wura ati okuta kristali kò to ẹgbẹ́ rẹ̀, bẹ̃li a kò le fi ohun èlo wura ṣe paṣiparọ rẹ̀.
18. A kò le idarukọ iyun tabi okuta perli; iye ọgbọ́n si jù okuta rubi lọ.