1. NITOTỌ ipa-ilẹ fàdaka mbẹ, ati ibi ti nwọn a ma idà wura.
2. Ninu ilẹ li a gbe nwà irin, bàba li a si ndà lati inu okuta wá.
3. Enia li o pari òkunkun, o si ṣe awari okuta òkunkun ati ti inu ojiji ikú si iha gbogbo.
4. Nwọn wá iho ilẹ ti o jìn si awọn ti o ngbe oke, awọn ti ẹsẹ enia gbagbe nwọn rọ si isalẹ, nwọn rọ si isalẹ jina si awọn enia.
5. Bi o ṣe ti ilẹ ni, ninu rẹ̀ ni onjẹ ti ijade wá, ati ohun ti o wà nisalẹ li o yi soke bi ẹnipe iná.
6. Okuta ibẹ ni ibi okuta Safiri, o si ni erupẹ wura.
7. Ipa ọ̀na na ni ẹiyẹ kò mọ̀, ati oju gunugun kò ri i ri.
8. Awọn ọmọ kiniun kò rin ibẹ rí, bẹ̃ni kiniun ti nké ramuramu kò kọja nibẹ rí.
9. O fi ọwọ rẹ̀ le akọ apata, o yi oke-nla po lati idi rẹ̀ wá.
10. O si la ipa-odò ṣiṣàn ninu apata, oju rẹ̀ si ri ohun iyebiye gbogbo.
11. O si sé iṣàn odò ki o má ṣe kún akunya, o si mu ohun ti o lumọ hàn jade wá si imọlẹ.
12. Ṣugbọn nibo li a o gbe wá ọgbọ́n ri, nibo si ni ibi oye?
13. Enia kò mọ̀ iye rẹ̀, bẹ̃li a kò le iri i ni ilẹ awọn alãyè.
14. Ọgbun wipe, kò si ninu mi, omi-okun si wipe, kò si ninu mi.
15. A kò le fi wura rà a, bẹ̃li a kò le ifi òṣuwọn wọ̀n fadaka ni iye rẹ̀.
16. A kò le fi wura Ofiri diyele e, pẹlu okuta oniksi iyebiye, ati okuta Safiri.
17. Wura ati okuta kristali kò to ẹgbẹ́ rẹ̀, bẹ̃li a kò le fi ohun èlo wura ṣe paṣiparọ rẹ̀.
18. A kò le idarukọ iyun tabi okuta perli; iye ọgbọ́n si jù okuta rubi lọ.
19. Okuta topasi ti Etiopia kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀, bẹ̃li a kò le ifi wura daradara diye le e.
20. Nibo ha li ọgbọn ti jade wá; tabi nibo ni ibi oye?
21. A ri pe, o lumọ kuro li oju awọn alãyè gbogbo, o si fara sin fun ẹiyẹ oju ọrun.
22. Ibi iparun (Abaddoni) ati ikú wipe, Awa ti fi etí wa gburo rẹ̀.
23. Ọlọrun li o moye ipa ọ̀na rẹ̀, o si mọ̀ ipo rẹ̀,
24. Nitoripe o woye de opin aiye, o si ri gbogbo isalẹ ọrun.
25. Lati dà òṣuwọn fun afẹfẹ, o si fi òṣuwọn wọ̀n omiyomi.
26. Nigbati o paṣẹ fun òjo, ti o si la ọ̀na fun mànamana ãrá:
27. Nigbana li o ri i, o si sọ ọ jade, o pèse rẹ̀ silẹ, ani o si wadi rẹ̀ ri.
28. Ati fun enia li o wipe, kiyesi i; Ẹru Oluwa, eyi li ọgbọ́n, ati lati jade kuro ninu ìwa-buburu eyi li oye!