Job 28:11-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. O si sé iṣàn odò ki o má ṣe kún akunya, o si mu ohun ti o lumọ hàn jade wá si imọlẹ.

12. Ṣugbọn nibo li a o gbe wá ọgbọ́n ri, nibo si ni ibi oye?

13. Enia kò mọ̀ iye rẹ̀, bẹ̃li a kò le iri i ni ilẹ awọn alãyè.

14. Ọgbun wipe, kò si ninu mi, omi-okun si wipe, kò si ninu mi.

15. A kò le fi wura rà a, bẹ̃li a kò le ifi òṣuwọn wọ̀n fadaka ni iye rẹ̀.

16. A kò le fi wura Ofiri diyele e, pẹlu okuta oniksi iyebiye, ati okuta Safiri.

17. Wura ati okuta kristali kò to ẹgbẹ́ rẹ̀, bẹ̃li a kò le fi ohun èlo wura ṣe paṣiparọ rẹ̀.

18. A kò le idarukọ iyun tabi okuta perli; iye ọgbọ́n si jù okuta rubi lọ.

19. Okuta topasi ti Etiopia kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀, bẹ̃li a kò le ifi wura daradara diye le e.

20. Nibo ha li ọgbọn ti jade wá; tabi nibo ni ibi oye?

21. A ri pe, o lumọ kuro li oju awọn alãyè gbogbo, o si fara sin fun ẹiyẹ oju ọrun.

22. Ibi iparun (Abaddoni) ati ikú wipe, Awa ti fi etí wa gburo rẹ̀.

Job 28