Joṣ 4:11-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. O si ṣe, nigbati gbogbo awọn enia na rekọja tán, ni apoti OLUWA rekọja, ati awọn alufa, li oju awọn enia.

12. Awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, si rekọja ni ihamọra niwaju awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi Mose ti sọ fun wọn:

13. Ìwọn ọkẹ meji enia ti o mura ogun, rekọja niwaju OLUWA fun ogun, si pẹtẹlẹ̀ Jeriko.

14. Li ọjọ́ na OLUWA gbé Joṣua ga li oju gbogbo Israeli: nwọn si bẹ̀ru rẹ̀, gẹgẹ bi nwọn ti bẹ̀ru Mose li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo.

15. OLUWA si wi fun Joṣua pe,

16. Paṣẹ fun awọn alufa ti o rù apoti ẹri nì pe, ki nwọn ki o ti inu Jordani jade.

17. Nitorina Joṣua paṣẹ fun awọn alufa wipe, Ẹ ti inu Jordani jade.

18. O si ṣe, nigbati awọn alufa ti o rù apoti majẹmu OLUWA ti ãrin Jordani jade, ti awọn alufa si gbé atẹlẹsẹ̀ wọn soke si ilẹ gbigbẹ, ni omi Jordani pada si ipò rẹ̀, o si ṣàn bò gbogbo bèbe rẹ̀, gẹgẹ bi ti iṣaju.

19. Awọn enia si ti inu Jordani gòke ni ijọ́ kẹwa oṣù kini, nwọn si dó ni Gilgali, ni ìha ìla-õrùn Jeriko.

20. Ati okuta mejila wọnni ti nwọn gbé ti inu Jordani lọ, ni Joṣua tòjọ ni Gilgali.

21. O si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Nigbati awọn ọmọ nyin yio bère lọwọ awọn baba wọn lẹhin ọ̀la wipe, Ẽredi okuta wọnyi?

22. Nigbana li ẹnyin o jẹ ki awọn ọmọ nyin ki o mọ̀ pe, Israeli là Jordani yi kọja ni ilẹ gbigbẹ.

23. Nitoriti OLUWA Ọlọrun nyin mu omi Jordani gbẹ kuro niwaju nyin, titi ẹnyin fi là a kọja, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun nyin ti ṣe si Okun Pupa, ti o mu gbẹ kuro niwaju wa, titi awa fi là a kọja:

Joṣ 4