Joṣ 22:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA ni Joṣua pè awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse,

2. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti ṣe gbogbo eyiti Mose iranṣẹ OLUWA palaṣẹ fun nyin, ẹnyin si gbọ́ ohùn mi ni gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun nyin:

3. Ẹnyin kò fi awọn arakunrin nyin silẹ lati ọjọ́ pipọ̀ wọnyi wá titi o fi di oni, ṣugbọn ẹnyin ṣe afiyesi ìlo ofin OLUWA Ọlọrun nyin.

4. Njẹ nisisiyi OLUWA Ọlọrun nyin ti fi isimi fun awọn arakunrin nyin, gẹgẹ bi o ti sọ fun wọn: njẹ nisisiyi ẹ pada, ki ẹ si lọ sinu agọ́ nyin, ati si ilẹ-iní nyin, ti Mose iranṣẹ OLUWA ti fun nyin ni ìha keji Jordani.

Joṣ 22