1. NIGBANA ni Joṣua pè awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse,
2. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti ṣe gbogbo eyiti Mose iranṣẹ OLUWA palaṣẹ fun nyin, ẹnyin si gbọ́ ohùn mi ni gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun nyin:
3. Ẹnyin kò fi awọn arakunrin nyin silẹ lati ọjọ́ pipọ̀ wọnyi wá titi o fi di oni, ṣugbọn ẹnyin ṣe afiyesi ìlo ofin OLUWA Ọlọrun nyin.