7. Awọn ọmọ Merari gẹgẹ bi idile wọn, ní ilu mejila, lati inu ẹ̀ya Reubeni, ati inu ẹ̀ya Gadi, ati lati inu ẹ̀ya Sebuluni.
8. Awọn ọmọ Israeli fi keké fun awọn ọmọ Lefi ni ilu wọnyi pẹlu àgbegbe wọn, gẹgẹ bi OLUWA ti palaṣẹ lati ọwọ́ Mose wá.
9. Nwọn si fi ilu ti a darukọ wọnyi fun wọn, lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Juda, ati lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni wá:
10. Nwọn si jẹ́ ti awọn ọmọ Aaroni, ni idile awọn ọmọ Kohati, ti mbẹ ninu awọn ọmọ Lefi, nitoriti nwọn ní ipín ikini.
11. Nwọn si fi Kiriati-arba, ti iṣe Hebroni fun wọn, (Arba ni baba Anaki ni ilẹ òke Juda,) pẹlu àgbegbe rẹ̀ yi i kakiri.