17. Lati òke Halaki lọ, ti o lọ soke Seiri, ani dé Baali-gadi ni afonifoji Lebanoni nisalẹ òke Hermoni: ati gbogbo awọn ọba wọn li o kó, o si kọlù wọn, o si pa wọn.
18. Joṣua si bá gbogbo awọn ọba wọnni jagun li ọjọ́ pipọ̀.
19. Kò sí ilu kan ti o bá awọn ọmọ Israeli ṣọrẹ, bikoṣe awọn Hifi awọn ara ilu Gibeoni: gbogbo wọn ni nwọn fi ogun gbà.
20. Nitori lati ọdọ OLUWA li a ti mu ọkàn wọn le, ki nwọn ki o le jade ogun tọ̀ Israeli wá, ki o le pa wọn run patapata, ki nwọn ki o má si ṣe ri ojurere, ṣugbọn ki o le pa wọn run, gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.
21. Li akokò na ni Joṣua wá, ti o si ke awọn ọmọ Anaki kuro ni ilẹ òke, kuro ni Hebroni, kuro ni Debiri, kuro ni Anabu, ati kuro ni gbogbo ilẹ òke Juda, ati kuro ni gbogbo ilẹ òke Israeli: Joṣua run wọn patapata pẹlu ilu wọn.
22. Kò kù ẹnikan ninu awọn ọmọ Anaki ni ilẹ awọn ọmọ Israeli: bikoṣe ni Gasa, ni Gati, ati ni Aṣdodu, ni nwọn kù si.
23. Bẹ̃ni Joṣua gbà gbogbo ilẹ na, gẹgẹ bi ohun gbogbo ti OLUWA ti wi fun Mose; Joṣua si fi i fun Israeli ni ilẹ-iní, gẹgẹ bi ipín wọn nipa ẹ̀ya wọn. Ilẹ na si simi lọwọ ogun.