Nitori lati ọdọ OLUWA li a ti mu ọkàn wọn le, ki nwọn ki o le jade ogun tọ̀ Israeli wá, ki o le pa wọn run patapata, ki nwọn ki o má si ṣe ri ojurere, ṣugbọn ki o le pa wọn run, gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.