14. Ṣugbọn nwọn ti rin nipa agidi ọkàn wọn ati nipasẹ Baalimu, ti awọn baba wọn kọ́ wọn:
15. Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi; sa wò o, awọn enia yi pãpa ni emi o fi wahala bọ́, emi o si mu wọn mu omi orõro.
16. Emi o si tú wọn ka ninu awọn keferi, ti awọn tikarawọn ati baba wọn kò mọ ri, emi o si rán idà si wọn titi emi o fi run wọn.
17. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Ẹ kiye si i, ki ẹ si pe awọn obinrin ti nṣọfọ, ki nwọn wá; ẹ si ranṣẹ pè awọn obinrin ti o moye, ki nwọn wá.
18. Ki nwọn ki o si yara, ki nwọn pohùnrere ẹkun fun wa, ki oju wa ki o le sun omije ẹkun, ati ki ipenpeju wa le tu omi jade.
19. Nitori a gbọ́ ohùn ẹkun lati Sioni, pe, A ti pa wa run to! awa dãmu jọjọ, nitoriti a kọ̀ ilẹ yi silẹ, nitoriti ibugbe wa tì wa jade.
20. Njẹ ẹnyin obinrin, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹ jẹ ki eti nyin gbọ́ ọ̀rọ ẹnu rẹ̀, ki ẹ si kọ́ ọmọbinrin nyin ni ẹkun, ati ki olukuluku obinrin ki o kọ́ aladugbo rẹ̀ ni arò.