8. Gbọ́ ẹkọ́, Jerusalemu, ki ẹmi mi ki o má ba lọ kuro lọdọ rẹ; ki emi má ba sọ ọ di ahoro, ilẹ ti a kò gbe inu rẹ̀.
9. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, jẹ ki nwọn ki o pẽṣẹ iyokù Israeli bi àjara: yi ọwọ rẹ pada bi aká-eso-ajara sinu agbọ̀n.
10. Tani emi o sọ fun, ti emi o kilọ fun ti nwọn o si gbọ́? sa wò o, eti wọn jẹ alaikọla, nwọn kò si le fi iye si i: sa wò o, ọ̀rọ Oluwa di ẹ̀gan si wọn, nwọn kò ni inu didùn ninu rẹ̀.
11. Nitorina emi kún fun ikannu Oluwa, ãrẹ̀ mu mi lati pa a mọra: tu u jade sori ọmọde ni ita, ati sori ajọ awọn ọmọkunrin pẹlu: nitori a o mu bãle pẹlu aya rẹ̀ ni igbekun, arugbo pẹlu ẹniti o ni ọjọ kikún lori.
12. Ile wọn o di ti ẹlomiran, oko wọn ati aya wọn lakopọ̀: nitori emi o nà ọwọ mi si ori awọn olugbe ilẹ na, li Oluwa wi.
13. Lati kekere wọn titi de nla wọn, gbogbo wọn li o fi ara wọn fun ojukokoro, ati lati woli titi de alufa, gbogbo wọn ni nṣe eke.
14. Nwọn si ti wo ọgbẹ ọmọbinrin enia mi fẹrẹ̀; nwọn wipe, Alafia! Alafia! nigbati kò si alafia.
15. A mu itiju ba wọn, nitoriti nwọn ṣe ohun irira: sibẹ nwọn kò tiju kan pẹlu, pẹlupẹlu õru itiju kò mu wọn: nitorina nwọn o ṣubu lãrin awọn ti o ṣubu: nigbati emi ba bẹ̀ wọn wo, a o wó wọn lulẹ, li Oluwa wi.
16. Bayi li Oluwa wi, ẹ duro li oju ọ̀na, ki ẹ si wò, ki ẹ si bere oju-ọ̀na igbàni, ewo li ọ̀na didara, ki ẹ si rin nibẹ, ẹnyin o si ri isimi fun ọkàn nyin. Ṣugbọn nwọn wipe, Awa kì yio rin.
17. Pẹlupẹlu mo fi oluṣọ sọdọ nyin, ti o wipe, Ẹ fi eti si iro fère. Ṣugbọn nwọn wipe, awa kì yio feti si i.
18. Nitorina, gbọ́, ẹnyin orilẹ-ède, ki ẹ si mọ̀, ẹnyin ijọ enia, ohun ti o wà ninu wọn!
19. Gbọ́, iwọ ilẹ! wò o, emi o mu ibi wá si ori enia yi, ani eso iro inu wọn, nitori nwọn kò fi eti si ọ̀rọ mi, ati ofin mi ni nwọn kọ̀ silẹ.
20. Ère wo li o wà fun mi ninu turari lati Ṣeba wá, ati ẽsu daradara lati ilẹ ti o jina wá? ọrẹ sisun nyin kò ṣe inu-didun mi, ẹbọ jijẹ nyin kò wù mi.
21. Nitorina, bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi o fi ohun idugbolu siwaju awọn enia yi, ti baba ati awọn ọmọ yio jumọ ṣubu lù wọn, aladugbo ati ọrẹ rẹ̀ yio ṣegbe.