10. Ọba Babeli si pa awọn ọmọ Sedekiah niwaju rẹ̀: o pa gbogbo awọn ọlọla Juda pẹlu ni Ribla.
11. Pẹlupẹlu ọba Babeli fọ Sedekiah li oju; o si fi ẹ̀wọn dè e, o si mu u lọ si Babeli, o si fi sinu tubu titi di ọjọ ikú rẹ̀.
12. Njẹ li oṣu karun, li ọjọ kẹwa oṣu, ti o jẹ ọdun kọkandilogun Nebukadnessari, ọba Babeli, ni Nebusaradani, balogun iṣọ, ti o nsin ọba Babeli, wá si Jerusalemu.
13. O si kun ile Oluwa, ati ile ọba; ati gbogbo ile Jerusalemu, ati gbogbo ile nla li o fi iná sun.
14. Ati gbogbo ogun awọn ara Kaldea, ti nwọn wà pẹlu balogun iṣọ, wó gbogbo odi Jerusalemu lulẹ yikakiri.
15. Nebusaradani, balogun iṣọ, si kó ninu awọn talaka awọn enia, ati iyokù awọn enia ti o kù ni ilu, ni igbekun lọ si Babeli, pẹlu awọn ti o ya lọ, ti o si ya tọ̀ ọba Babeli lọ, ati iyokù awọn ọ̀pọ enia na.
16. Nebusaradani, balogun iṣọ, si fi ninu awọn talaka ilẹ na silẹ lati mã ṣe alabojuto ajara ati lati ma ṣe alaroko.
17. Ati ọwọ̀n idẹ wọnni ti mbẹ lẹba ile Oluwa, ati ijoko wọnni ati agbada idẹ nla ti o wà ni ile Oluwa ni awọn ara Kaldea fọ tũtu, nwọn si kó gbogbo idẹ wọn lọ si Babeli.
18. Ati ìkoko wọnni, ati ọkọ́ wọnni, ati alumagaji fitila wọnni, ati ọpọ́n wọnni, ati ṣibi wọnni, ati gbogbo ohun elo idẹ wọnni ti nwọn fi nṣiṣẹ isin, ni nwọn kó lọ.