1. SEDEKIAH jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun nigbati o bẹrẹ si ijọba, o si jọba, ọdun mọkanla ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Hamutali, ọmọbinrin Jeremiah, ara Libna.
2. On si ṣe buburu niwaju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jehoiakimu ti ṣe.
3. Nitori ibinu Oluwa, o ri bẹ̃ ni Jerusalemu ati Juda, titi o fi tì wọn jade kuro niwaju rẹ̀. Sedekiah si ṣọtẹ si ọba Babeli.
4. O si ṣe li ọdun kẹsan ijọba rẹ̀, li oṣu kẹwa, li ọjọ kẹwa oṣu, Nebukadnessari, ọba Babeli de, on ati gbogbo ogun rẹ̀ si Jerusalemu, o si dó tì i, o si mọdi tì i yikakiri.
5. A si há ilu na mọ titi di ọdun ikọkanla Sedekiah ọba.
6. Ati li oṣu kẹrin li ọjọ kẹsan oṣu, ìyan mu gidigidi ni ilu, tobẹ̃ ti kò si onjẹ fun awọn enia ilẹ na.
7. Nigbana ni a fọ ilu, gbogbo awọn ologun si sá, nwọn si jade ni ilu li oru, nwọn gba ọ̀na ẹnu ibode ãrin odi meji, ti o wà li ẹba ọgbà ọba, ṣugbọn awọn ara Kaldea yi ilu ka: nwọn si jade lọ li ọ̀na pẹtẹlẹ.