Jer 51:51-64 Yorùbá Bibeli (YCE)

51. Oju tì wa, nitoripe awa ti gbọ́ ẹ̀gan: itiju ti bò loju, nitori awọn alejo wá sori ohun mimọ́ ile Oluwa.

52. Nitorina, wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o ṣe ibẹwo lori awọn ere fifin rẹ̀: ati awọn ti o gbọgbẹ yio si mã gbin ja gbogbo ilẹ rẹ̀.

53. Bi Babeli tilẹ goke lọ si ọrun, bi o si ṣe olodi li oke agbara rẹ̀, sibẹ awọn afiniṣeijẹ yio ti ọdọ mi tọ̀ ọ wá, li Oluwa wi.

54. Iró igbe lati Babeli! ati iparun nla lati ilẹ awọn ara Kaldea!

55. Nitoripe Oluwa ti ṣe Babeli ni ijẹ, o si ti pa ohùn nla run kuro ninu rẹ̀; riru wọn si nho bi omi pupọ, a gbọ́ ariwo ohùn wọn.

56. Nitoripe afiniṣeijẹ de sori rẹ̀, ani sori Babeli; a mu awọn akọni rẹ̀, a ṣẹ́ gbogbo ọrun wọn: nitori Ọlọrun ẹsan ni Oluwa, yio san a nitõtọ.

57. Emi o si mu ki awọn ijoye rẹ̀ yo bi ọ̀muti, ati awọn ọlọgbọn rẹ̀, awọn bàlẹ rẹ̀, ati awọn alakoso rẹ̀, ati awọn akọni rẹ̀, nwọn o si sun orun lailai, nwọn kì o si ji mọ́, li Ọba wi, ẹniti orukọ rẹ̀ ijẹ Oluwa awọn ọmọ-ogun.

58. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: odi Babeli gbigboro li a o wó lulẹ patapata, ẹnu-bode giga rẹ̀ li a o si fi iná sun: tobẹ̃ ti awọn enia ti ṣiṣẹ lasan, ati awọn orilẹ-ède ti ṣiṣẹ fun iná, ti ãrẹ si mu wọn.

59. Ọ̀rọ ti Jeremiah woli paṣẹ fun Seraiah, ọmọ Neriah, ọmọ Maaseiah, nigbati o nlọ niti Sedekiah, ọba Judah, si Babeli li ọdun kẹrin ijọba rẹ̀. Seraiah yi si ni ijoye ibudo.

60. Jeremiah si kọ gbogbo ọ̀rọ-ibi ti yio wá sori Babeli sinu iwe kan, ani gbogbo ọ̀rọ wọnyi ti a kọ si Babeli.

61. Jeremiah si sọ fun Seraiah pe, nigbati iwọ ba de Babeli, ki iwọ ki o si wò, ki iwọ ki o si ka gbogbo ọ̀rọ wọnyi.

62. Ki iwọ ki o si wipe, Oluwa, iwọ ti sọ̀rọ si ibi yi, lati ke e kuro, ki ẹnikẹni má ṣe gbe inu rẹ̀, ati enia ati ẹran, nitori pe yio di ahoro lailai.

63. Yio si ṣe nigbati iwọ ba pari kikà iwe yi tan, ki iwọ ki o di okuta mọ ọ, ki o si sọ ọ si ãrin odò Ferate:

64. Ki iwọ si wipe, Bayi ni Babeli yio rì, kì o si tun dide kuro ninu ibi ti emi o mu wá sori rẹ̀: ãrẹ̀ yio si mu wọn. Titi de ihin li ọ̀rọ Jeremiah.

Jer 51