11. Pọ́n ọfa mu: mu asà li ọwọ: Oluwa ti ru ẹmi awọn ọba Media soke: nitori ipinnu rẹ̀ si Babeli ni lati pa a run, nitoripe igbẹsan Oluwa ni, igbẹsan fun tempili rẹ̀.
12. Gbé asia soke lori odi Babeli, mu awọn iṣọ lagbara, mu awọn oluṣọ duro, ẹ yàn ẹ̀bu: nitori Oluwa gbero, o si ṣe eyi ti o wi si awọn olugbe Babeli.
13. Iwọ ẹniti ngbe ẹba omi pupọ, ti o pọ ni iṣura, opin rẹ de, iwọn ikogun-ole rẹ kún.
14. Oluwa awọn ọmọ-ogun ti fi ẹmi rẹ̀ bura pe, ni kikún emi o fi enia kún ọ gẹgẹ bi ẹlẹnga; nwọn o si pa ariwo ogun lori rẹ.
15. On ti da aiye nipa agbara rẹ̀, on ti ṣe ipinnu araiye nipa ọgbọ́n rẹ̀, o si tẹ́ awọn ọrun nipa oye rẹ̀.
16. Nigbati o ba san ãrá, ọ̀pọlọpọ omi ni mbẹ li oju ọrun; o si mu kũku goke lati opin aiye wá, o dá manamana fun òjo, o si mu ẹfũfu jade lati inu iṣura rẹ̀ wá.
17. Aṣiwere ni gbogbo enia, nitori oye kò si; oju tì gbogbo alagbẹdẹ nitori ere, nitori ere didà rẹ̀ eke ni, kò si sí ẹmi ninu wọn.
18. Asan ni nwọn, ati iṣẹ iṣina: ni ìgba ibẹ̀wo wọn, nwọn o ṣegbe.
19. Ipin Jakobu kò dabi wọn: nitori on ni iṣe Ẹlẹda ohun gbogbo: Israeli si ni ẹ̀ya ijogun rẹ̀: Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.
20. Iwọ ni òlù mi, ohun elo-ogun: emi o fi ọ fọ awọn orilẹ-ède tũtu, emi o si fi ọ pa awọn ijọba run;
21. Emi o si fi ọ fọ ẹṣin ati ẹlẹṣin tũtu; emi o si fi ọ fọ kẹ̀kẹ ati ẹniti o gùn u tũtu;
22. Emi o si fi ọ fọ ọkunrin ati obinrin tũtu; emi o si fi ọ fọ arugbo ati ọmọde tũtu; emi o si fi ọ fọ ọdọmọkunrin ati wundia tũtu;