Jer 50:33-46 Yorùbá Bibeli (YCE)

33. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, pe, awọn ọmọ Israeli ati awọn ọmọ Juda li a jumọ pọn loju pọ̀: gbogbo awọn ti o kó wọn ni ìgbekun si di wọn mu ṣinṣin; nwọn kọ̀ lati jọ wọn lọwọ lọ.

34. Ṣugbọn Olurapada wọn lagbara; Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀: ni jijà yio gba ijà wọn jà! ki o le mu ilẹ na simi, ki o si mu awọn olugbe Babeli wariri.

35. Ida lori awọn ara Kaldea, li Oluwa wi, ati lori awọn olugbe Babeli, ati lori awọn ijoye rẹ̀, ati lori awọn ọlọgbọn rẹ̀?

36. Idà lori awọn ahalẹ nwọn o si ṣarán: idà lori awọn alagbara rẹ̀; nwọn o si damu.

37. Idà lori awọn ẹṣin rẹ̀, ati lori awọn kẹ̀kẹ ati lori gbogbo awọn àjeji enia ti o wà lãrin rẹ̀; nwọn o si di obinrin: idà lori iṣura rẹ̀; a o si kó wọn lọ.

38. Ọda lori omi odò rẹ̀; nwọn o si gbẹ: nitori ilẹ ere fifin ni, nwọn si nṣogo ninu oriṣa wọn.

39. Nitorina awọn ẹran-iju pẹlu ọ̀wawa ni yio ma gbe ibẹ̀, abo ògongo yio si ma gbe inu rẹ̀, a kì o si gbe inu rẹ̀ mọ lailai; bẹ̃ni a kì o ṣatipo ninu rẹ̀ lati irandiran.

40. Gẹgẹ bi Ọlọrun ti bì Sodomu ati Gomorra ṣubu ati awọn aladugbo rẹ̀, li Oluwa wi; bẹ̃ni enia kan kì o gbe ibẹ, tabi ọmọ enia kan kì o ṣatipo ninu rẹ̀.

41. Wò o, orilẹ-ède kan yio wá lati ariwa, ati orilẹ-ède nla, ọba pupọ li o si dide lati opin ilẹ aiye wá.

42. Nwọn o di ọrun ati ọ̀kọ mu: onroro ni nwọn, nwọn kì o si ṣe ãnu: ohùn wọn yio ho gẹgẹ bi okun, nwọn o si gun ori ẹṣin lẹsẹsẹ, nwọn si mura bi ọkunrin ti yio jà ọ logun, iwọ ọmọbinrin Babeli.

43. Ọba Babeli ti gbọ́ iró wọn, ọwọ rẹ̀ si rọ: ẹ̀dun dì i mu, ati irora gẹgẹ bi obinrin ti nrọbi.

44. Wò o, on o goke wá bi kiniun lati wiwú Jordani si ibugbe okuta; nitori ojiji li emi o le wọn lọ kuro nibẹ; ati tani si li ẹniti a yàn, ti emi o yàn sori rẹ̀? nitori tani dabi emi? tani o si pè mi ṣe ẹlẹri? ati tani oluṣọ-agutan na ti yio le duro niwaju mi?

45. Nitorina gbọ́ ìmọ Oluwa, ti o ti gba si Babeli: ati èro rẹ̀, ti o ti gba si ilẹ awọn ara Kaldea: lõtọ awọn ti o kere julọ ninu agbo-ẹran: yio wọ́ wọn kiri: lõtọ on o sọ ibugbe di ahoro lori wọn.

46. Nitori ohùn igbe nla pe: a kó Babeli, ilẹ-aiye mì, a si gbọ́ ariwo na lãrin awọn orilẹ-ède.

Jer 50