Gẹgẹ bi Ọlọrun ti bì Sodomu ati Gomorra ṣubu ati awọn aladugbo rẹ̀, li Oluwa wi; bẹ̃ni enia kan kì o gbe ibẹ, tabi ọmọ enia kan kì o ṣatipo ninu rẹ̀.