20. Kede eyi ni ile Jakobu, pokiki rẹ̀ ni Juda wipe,
21. Ẹ gbọ́ eyi nisisiyi, ẹnyin aṣiwere enia ati alailọgbọ́n; ti o ni oju, ti kò si riran, ti o ni eti ti kò si gbọ́.
22. Ẹ kò ha bẹ̀ru mi; li Oluwa wi, ẹ kì yio warìri niwaju mi, ẹniti o fi yanrin ṣe ipãla okun, opin lailai ti kò le rekọja: ìgbì rẹ̀ kọlu u, kò si le bori rẹ̀, o pariwo, ṣugbọn kò lè re e kọja?
23. Ṣugbọn enia yi ni aiya isàgun ati iṣọtẹ si, nwọn sọ̀tẹ, nwọn si lọ.
24. Bẹ̃ni nwọn kò wi li ọkàn wọn pe, Ẹ jẹ ki a bẹ̀ru Oluwa Ọlọrun wa wayi, ẹniti o fun wa ni òjo akọrọ ati arọkuro ni igba rẹ̀: ti o fi ọ̀sẹ ikore ti a pinnu pamọ fun wa.
25. Aiṣedede nyin ti yi gbogbo ohun wọnyi pada, ati ẹ̀ṣẹ nyin ti fà ohun rere sẹhin kuro lọdọ nyin.
26. Nitori lãrin enia mi ni a ri enia ìka, nwọn wò kakiri, bi biba ẹniti ndẹ ẹiyẹ, nwọn dẹ okùn nwọn mu enia.
27. Bi àgo ti o kún fun ẹiyẹ, bẹ̃ni ile wọn kún fun ẹ̀tan, nitorina ni nwọn ṣe di nla, nwọn si di ọlọrọ̀.
28. Nwọn sanra, nwọn ndán, pẹlupẹlu nwọn rekọja ni ìwa-buburu, nwọn kò ṣe idajọ, nwọn kò dajọ ọ̀ran alainibaba, ki nwọn le ri rere; nwọn kò si dajọ are awọn talaka.
29. Emi kì yio ha ṣe ibẹwò nitori nkan wọnyi, li Oluwa wi, ẹmi mi kì yio ha gbẹsan lori orilẹ-ède bi eyi?
30. Ohun iyanu ati irira li a ṣe ni ilẹ na.
31. Awọn woli sọ asọtẹlẹ eke, ati awọn alufa ṣe akoso labẹ ọwọ wọn, awọn enia mi si fẹ ki o ri bẹ̃; kini ẹnyin o si ṣe ni igbẹhin rẹ̀?