34. Lati igbe Heṣboni de Eleale, de Jahasi, ni nwọn fọ ohùn wọn, lati Soari de Horonaimu, ti iṣe ẹgbọrọ malu ọlọdun mẹta, nitori omi Nimrimu pẹlu yio dahoro.
35. Emi o si mu ki o dopin ni Moabu, li Oluwa wi: ẹniti o nrubọ ni ibi giga, ati ẹniti nsun turari fun oriṣa rẹ̀.
36. Nitorina ni ọkàn mi ró fun Moabu bi fère, ọkàn mi yio si ró bi fere fun awọn ọkunrin Kirheresi: nitori iṣura ti o kojọ ṣegbe.
37. Nitori gbogbo ori ni yio pá, ati gbogbo irungbọn li a o ke kù: ọgbẹ yio wà ni gbogbo ọwọ, ati aṣọ-ọ̀fọ ni ẹgbẹ mejeji.
38. Ẹkún nlanla ni yio wà lori gbogbo orule Moabu, ati ni ita rẹ̀: nitori emi ti fọ́ Moabu bi ati ifọ́ ohun-elo, ti kò wù ni, li Oluwa wi.
39. Ẹ hu, pe, bawo li a ti wo o lulẹ! bawo ni Moabu ti fi itiju yi ẹhin pada! bẹ̃ni Moabu yio di ẹ̀gan ati idãmu si gbogbo awọn ti o yi i kakiri.
40. Nitori bayi li Oluwa wi; Wò o, on o fò gẹgẹ bi idi, yio si nà iyẹ rẹ̀ lori Moabu.
41. A kó Kerioti, a si kó awọn ilu olodi, ati ọkàn awọn akọni Moabu li ọjọ na yio dabi ọkàn obinrin ninu irọbi rẹ̀.
42. A o si pa Moabu run lati má jẹ orilẹ-ède, nitoripe o ti gberaga si Oluwa.
43. Ẹ̀ru, ati ọ̀fin, ati okùn-didẹ, yio wà lori rẹ iwọ olugbe Moabu, li Oluwa wi.
44. Ẹniti o ba sa fun ẹ̀ru yio ṣubu sinu ọ̀fin; ati ẹniti o ba jade kuro ninu ọ̀fin ni a o mu ninu okùn-didẹ: nitori emi o mu wá sori rẹ̀, ani sori Moabu, ọdun ibẹ̀wo wọn, li Oluwa wi.
45. Awọn ti o sá, duro li aini agbara labẹ ojiji Heṣboni: ṣugbọn iná yio jade wá lati Heṣboni, ati ọwọ-iná lati ãrin Sihoni, yio si jẹ ilẹ Moabu run, ati agbari awọn ọmọ ahoro.
46. Egbe ni fun ọ, iwọ Moabu! orilẹ-ède Kemoṣi ṣegbe: nitori a kó awọn ọkunrin rẹ ni igbekun, ati awọn ọmọbinrin rẹ ni igbekun.
47. Sibẹ emi o tun mu igbekun Moabu pada li ọjọ ikẹhin, li Oluwa wi. Titi de ihin ni idajọ Moabu.