Ẹniti o ba sa fun ẹ̀ru yio ṣubu sinu ọ̀fin; ati ẹniti o ba jade kuro ninu ọ̀fin ni a o mu ninu okùn-didẹ: nitori emi o mu wá sori rẹ̀, ani sori Moabu, ọdun ibẹ̀wo wọn, li Oluwa wi.