13. Moabu yio si tiju nitori Kemoṣi, gẹgẹ bi ile Israeli ti tiju nitori Beteli, igbẹkẹle wọn.
14. Ẹnyin ha ṣe wipe, akọni ọkunrin ni awa, alagbara fun ogun?
15. A fi Moabu ṣe ijẹ, ẽfin ilu rẹ̀ si goke lọ, awọn àṣayan ọdọmọkunrin rẹ̀ si sure lọ si ibi pipa, li Ọba wi, ẹniti orukọ rẹ̀ ijẹ, Oluwa awọn ọmọ-ogun.
16. Wahala Moabu sunmọ tosi lati de, ipọnju rẹ̀ si nyara kánkan.
17. Gbogbo ẹnyin ti o wà yi i ka, ẹ kedaro rẹ̀; ati gbogbo ẹnyin ti o mọ̀ orukọ rẹ̀, ẹ wipe, bawo li ọpa agbara rẹ fi ṣẹ́, ọpa ogo!
18. Iwọ olugbe ọmọbinrin Diboni, sọkalẹ lati inu ogo, ki o si ma gbe ibi ongbẹ; nitori afiniṣe-ijẹ. Moabu yio goke wá sori rẹ, yio si pa ilu olodi rẹ run.