20. Nitori ọkàn nyin li ẹnyin tanjẹ, nigbati ẹnyin rán mi si Oluwa, Ọlọrun nyin, wipe, Gbadura fun wa si Oluwa, Ọlọrun wa: ati gẹgẹ bi gbogbo eyi ti Oluwa Ọlọrun wa yio wi, bẹ̃ni ki o sọ fun wa, awa o si ṣe e.
21. Emi si ti sọ fun nyin loni; ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́ ohùn Oluwa, Ọlọrun nyin, ati gbogbo eyi ti on ti ran mi si nyin.
22. Njẹ nitorina, ẹ mọ̀ dajudaju pe, ẹnyin o kú nipa idà, nipa ìyan, ati nipa àjakalẹ-arun, ni ibẹ na nibiti ẹnyin fẹ lati lọ iṣe atipo.