Jer 42:16-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Yio si ṣe, idà ti ẹnyin bẹ̀ru, yio si le nyin ba ni ilẹ Egipti; ati ìyan, ti ẹnyin bẹ̀ru, yio tẹle nyin girigiri nibẹ ni Egipti; nibẹ li ẹnyin o si kú.

17. Bẹ̃ni gbogbo awọn ọkunrin ti nwọn gbe oju wọn si ati lọ si Egipti lati ṣatipo nibẹ; nwọn o kú, nipa idà, nipa ìyan, tabi nipa àjakalẹ-arun, ẹnikẹni ninu wọn kì yio kù, tabi kì o sala kuro ninu ibi ti emi o mu wá sori wọn.

18. Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, pe, Gẹgẹ bi emi ti dà ibinu mi ati irunu mi sori awọn olugbe Jerusalemu; bẹ̃ni emi o dà irunu mi le nyin lori, ẹnyin ti yio lọ si Egipti: ẹnyin o si di ẹni-ègun, ati ẹni-iyanu, ati ẹ̀gan, ati ẹ̀sin; ẹnyin kì yio si tun ri ibi yi mọ.

19. Oluwa ti sọ niti nyin, ẹnyin iyokù Juda, ẹ má lọ si Egipti: ẹ mọ̀ dajudaju pe emi ti jẹri si nyin li oni yi.

Jer 42