Jer 42:10-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Bi ẹnyin o ba gbe ilẹ yi lõtọ, nigbana ni emi o gbe nyin ro emi kì yio si fà nyin lulẹ, emi o si gbìn nyin, emi kì yio si fà nyin tu: nitori emi yi ọkàn pada niti ibi ti emi ti ṣe si nyin.

11. Ẹ má bẹ̀ru ọba Babeli, ẹniti ẹnyin mbẹ̀ru: ẹ máṣe bẹ̀ru rẹ̀, li Oluwa wi: nitori emi wà pẹlu nyin lati ràn nyin lọwọ, ati lati gbà nyin li ọwọ rẹ̀.

12. Emi o si fi ãnu hàn fun nyin, ki on ki o le ṣãnu fun nyin, ki o si mu ki ẹnyin pada si ilẹ nyin.

Jer 42