6. Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, si jade lati Mispa lọ ipade wọn, bi o ti nlọ, o nsọkun: o si ṣe, bi o ti pade wọn, o wi fun wọn pe, jẹ ki a lọ sọdọ Gedaliah, ọmọ Ahikamu.
7. O si ṣe, nigbati nwọn de ãrin ilu, ni Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, pa wọn, on, ati awọn ọkunrin ti o wà pẹlu rẹ̀ si sọ wọn sinu iho.
8. Ṣugbọn ọkunrin mẹwa wà lãrin wọn ti nwọn sọ fun Iṣmaeli pe, máṣe pa wa: nitori awa ni iṣura li oko, ti alikama, ati ti ọka barli, ati ti ororo, ati oyin. Bẹ̃li o jọwọ wọn, kò si pa wọn pẹlu awọn arakunrin wọn.
9. Ati iho na ninu eyi ti Iṣmaeli ti sọ gbogbo okú ọkunrin wọnyi si, awọn ti o ti pa pẹlu Gedaliah, ni eyiti Asa, ọba, ti ṣe nitori ibẹ̀ru Baaṣa, ọba Israeli: Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, si fi awọn ti a pa kún u.
10. Iṣmaeli si kó gbogbo iyokù awọn enia ti o wà ni Mispa ni igbekun, awọn ọmọbinrin ọba, ati gbogbo enia ti o kù ni Mispa, awọn ti Nebusaradani, balogun iṣọ, ti fi le Gedaliah, ọmọ Ahikamu lọwọ: Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, si kó wọn ni igbekun, o si kuro nibẹ lati rekọja lọ sọdọ awọn ọmọ Ammoni.
11. Ṣugbọn nigbati Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun ti o pẹlu rẹ̀, gbọ́ ibi ti Iṣmaeli, ọmọ Netaniah ti ṣe,