4. O si ṣe li ọjọ keji lẹhin ti o ti pa Gedaliah, ti ẹnikan kò si mọ̀.
5. Nigbana ni ọgọrin ọkunrin wá lati Ṣekemu, lati Ṣilo, ati lati Samaria, ti nwọn fá irungbọn wọn, nwọn fà aṣọ wọn ya, nwọn si ṣá ara wọn lọgbẹ, nwọn mu ọrẹ-ẹbọ ati turari li ọwọ wọn lati mu u wá si ile Oluwa.
6. Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, si jade lati Mispa lọ ipade wọn, bi o ti nlọ, o nsọkun: o si ṣe, bi o ti pade wọn, o wi fun wọn pe, jẹ ki a lọ sọdọ Gedaliah, ọmọ Ahikamu.