13. Ṣugbọn Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun ti o wà li oko, tọ̀ Gedaliah wá si Mispa.
14. Nwọn si wi fun u pe, Iwọ ha mọ̀ dajudaju pe: Baalisi, ọba awọn ọmọ Ammoni, ti ran Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, lati pa ọ? Ṣugbọn Gedaliah, ọmọ Ahikamu, kò gbà wọn gbọ́.
15. Nigbana ni Johanani, ọmọ Karea, si sọ nikọkọ fun Gedaliah ni Mispa pe, Jẹ ki emi lọ, mo bẹ ọ, emi o si pa Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, ẹnikan kì yio si mọ̀: Ẽṣe ti on o fi pa ọ, ti gbogbo awọn ara Juda ti a kojọ tì ọ, yio tuka, ati iyokù Juda yio ṣegbe?
16. Ṣugbọn Gedaliah, ọmọ Ahikamu, sọ fun Johanani, ọmọ Karea pe, Iwọ kò gbọdọ ṣe nkan yi, nitori eke ni iwọ ṣe mọ Iṣmaeli.