22. Nitori òpe li enia mi, nwọn kò mọ̀ mi; alaimoye ọmọ ni nwọn iṣe, nwọn kò si ni ìmọ: nwọn ni ọgbọ́n lati ṣe ibi, ṣugbọn oye ati ṣe rere ni nwọn kò ni.
23. Mo bojuwo aiye, sa wò o, o wà ni jũju, o si ṣofo; ati ọrun, imọlẹ kò si lara rẹ̀.
24. Mo bojuwo gbogbo oke nla, sa wò o, o warìri ati gbogbo oke kekere mì jẹjẹ.
25. Mo bojuwo, sa wò o, kò si enia kan, pẹlupẹlu gbogbo ẹiyẹ oju-ọrun sa lọ.
26. Mo bojuwo, sa wò o, Karmeli di aginju, ati gbogbo ilu rẹ̀ li o wó lulẹ, niwaju Oluwa ati niwaju ibinu rẹ̀ gbigbona.
27. Nitori bayi li Oluwa wi pe: Gbogbo ilẹ ni yio di ahoro; ṣugbọn emi kì yio ṣe ipari tan.
28. Nitori eyi ni ilẹ yio ṣe kãnu, ati ọrun loke yio di dudu: nitori emi ti wi i, mo ti pete rẹ̀, emi kì o yi ọkàn da, bẹ̃ni kì o yipada kuro ninu rẹ̀.
29. Gbogbo ilu ni yio sá nitori ariwo awọn ẹlẹṣin ati awọn tafatafa; nwọn o sa lọ sinu igbo; nwọn o si gun ori oke okuta lọ, gbogbo ilu ni a o kọ̀ silẹ, ẹnikan kì yio gbe inu wọn.