8. Awọn ara Kaldea si fi ile ọba ati ile awọn enia joná, nwọn si wó odi Jerusalemu lulẹ.
9. Nebusaradani, balogun iṣọ, si kó iyokù awọn enia ti o kù ni ilu ni igbekun lọ si Babeli, pẹlu awọn ti o ti ya lọ, ti o ya sọdọ rẹ̀, pẹlu awọn enia iyokù ti o kù.
10. Ṣugbọn Nebusaradani, balogun iṣọ, si mu diẹ ninu awọn enia, ani awọn talaka ti kò ni nkan rara, joko ni ilẹ Juda, o si fi ọgba-àjara ati oko fun wọn li àkoko na.
11. Nebukadnessari, ọba Babeli, si paṣẹ fun Nebusaradani, balogun iṣọ, niti Jeremiah, wipe,
12. Mu u, ki o si bojuto o, má si ṣe e ni ibi kan; ṣugbọn gẹgẹ bi on ba ti sọ fun ọ, bẹ̃ni ki iwọ ki o ṣe fun u.
13. Bẹ̃ni Nebusaradani, balogun iṣọ, ati Nebuṣaṣbani, olori iwẹfa, ati Nergali Ṣareseri, olori amoye, ati gbogbo ijoye ọba Babeli, si ranṣẹ,
14. Ani nwọn ranṣẹ nwọn si mu Jeremiah jade ni àgbala ile-tubu, nwọn si fi fun Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, pe ki o mu u lọ si ile: bẹ̃ni o ngbe ãrin awọn enia.