18. Baruku si da wọn lohùn pe; Lati ẹnu rẹ̀ li o si sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun mi, emi si fi tadawa kọ wọn sinu iwe na.
19. Nigbana ni awọn ijoye sọ fun Baruku pe, Lọ, fi ara rẹ pamọ, iwọ ati Jeremiah; má si jẹ ki ẹnikan mọ̀ ibi ti ẹnyin wà.
20. Nwọn si wọle tọ̀ ọba lọ ninu àgbala, ṣugbọn nwọn fi iwe-kiká na pamọ si iyara Eliṣama, akọwe, nwọn si sọ gbogbo ọ̀rọ na li eti ọba.
21. Ọba si rán Jehudu lati lọ mu iwe-kiká na wá: on si mu u jade lati inu iyara Eliṣama, akọwe. Jehudu si kà a li eti ọba, ati li eti gbogbo awọn ijoye, ti o duro tì ọba.
22. Ọba si ngbe ile igba-otutu li oṣu kẹsan: ina si njo niwaju rẹ̀ ninu idana.