18. Li ọjọ wọnnì, ile Juda yio rin pẹlu ile Israeli, nwọn o jumọ wá lati ilẹ ariwa, si ilẹ ti emi ti fi fun awọn baba nyin li ogún.
19. Emi si wipe, Bawo li emi o ṣe gbe ọ kalẹ pẹlu awọn ọmọ, ati lati fun ọ ni ilẹ ayanfẹ, ogún daradara, ani ogún awọn orilẹ-ède? Emi si wipe, Iwọ o pè mi ni, Baba mi! iwọ kì o si pada kuro lọdọ mi.
20. Nitõtọ gẹgẹ bi aya ti ifi arekereke lọ kuro lọdọ ọkọ rẹ̀, bẹ̃ni ẹnyin ti hùwa arekereke si mi, iwọ ile Israeli: li Oluwa wi.
21. A gbọ́ ohùn kan lori ibi giga, ẹkun, ani ẹ̀bẹ awọn ọmọ Israeli pe: nwọn ti bà ọ̀na wọn jẹ, nwọn si ti gbagbe Oluwa, Ọlọrun wọn.
22. Yipada, ẹnyin ọmọ apẹhinda, emi o si wò ipẹhinda nyin sàn; Sa wò o, awa tọ̀ ọ wá, nitori iwọ li Oluwa Ọlọrun wa!
23. Lotitọ asan ni eyi ti o ti oke wá, ani ọ̀pọlọpọ oke giga, lõtọ ninu Oluwa Ọlọrun wa ni igbala Israeli wà.
24. Ṣugbọn ohun itiju oriṣa ti jẹ ère iṣẹ awọn baba wa lati igba ewe wa wá, ọwọ́-ẹran wọn ati agbo-ẹran wọn, pẹlu ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn.
25. Awa dubulẹ ninu itiju wa, rudurudu wa bò wa mọlẹ, nitoriti awa ti ṣẹ̀ si Oluwa Ọlọrun wa, awa pẹlu awọn baba wa, lati igba ewe wa wá, titi di oni yi, awa kò gba ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́.