Jer 3:14-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Pada, ẹnyin apẹhinda ọmọ, li Oluwa wi, nitori emi gbe nyin ni iyawo; emi o si mu nyin, ọkan ninu ilu kan, ati meji ninu idile kan; emi o si mu nyin wá si Sioni.

15. Emi o si fun nyin li oluṣọ-agutan gẹgẹ bi ti inu mi, ti yio fi ìmọ ati oye bọ́ nyin.

16. Yio si ṣe nigbati ẹnyin ba pọ̀ si i, ti ẹ si dàgba ni ilẹ na, li ọjọ wọnnì, li Oluwa wi; nwọn kì yio si tun le wipe, Apoti-ẹri majẹmu Oluwa; bẹ̃ni kì yio wọ inu wọn, nwọn kì yio si ranti rẹ̀, nwọn kì yio tọ̀ ọ wá pẹlu, bẹ̃ni a kì yio si tun ṣe e mọ.

17. Nigbana ni nwọn o pè Jerusalemu ni itẹ Oluwa; gbogbo orilẹ-ède yio kọja tọ̀ ọ wá si orukọ Oluwa, si Jerusalemu, bẹ̃ni nwọn kì yio rìn mọ nipa agidi ọkàn buburu wọn,

18. Li ọjọ wọnnì, ile Juda yio rin pẹlu ile Israeli, nwọn o jumọ wá lati ilẹ ariwa, si ilẹ ti emi ti fi fun awọn baba nyin li ogún.

Jer 3