Jer 27:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI atetekọbẹrẹ ijọba Sedekiah, ọmọ Josiah, ọba Juda, li ọ̀rọ yi tọ̀ Jeremiah wá lati ọ̀dọ Oluwa wipe,

2. Bayi li Oluwa wi fun mi; Ṣe ijara ati àjaga-ọrùn fun ara rẹ, ki o si fi wọ ọrùn rẹ.

3. Ki o rán wọn lọ si ọdọ ọba Edomu, ati si ọba Moabu, ati si ọba awọn ọmọ Ammoni, ati si ọba Tire, ati si ọba Sidoni, lọwọ awọn ikọ̀ ti o wá si Jerusalemu sọdọ Sedekiah, ọba Juda.

4. Ki o si paṣẹ fun wọn lati wi fun awọn oluwa wọn pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, Bayi li ẹnyin o wi fun awọn oluwa nyin pe;

5. Emi ti dá aiye, enia ati ẹranko ti o wà lori ilẹ aiye, nipa agbara nla mi, ati nipa ọwọ ninà mi, emi si fi i fun ẹnikẹni ti o wù mi.

6. Njẹ nisisiyi, emi fi gbogbo ilẹ yi le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli, ọmọ-ọdọ mi: ati ẹranko igbẹ ni mo fi fun u pẹlu lati sin i.

7. Ati orilẹ-ède gbogbo ni yio sin on, ati ọmọ rẹ̀ ati ọmọ-ọmọ rẹ̀, titi di ìgba ti akoko ilẹ tirẹ̀ yio de; lara rẹ̀ ni orilẹ-ède pupọ ati awọn ọba nla yio jẹ.

8. Yio si ṣe, orilẹ-ède ati ijọba ti kì yio sin Nebukadnessari ọba Babeli, ti kì yio fi ọrùn wọn si abẹ àjaga ọba Babeli, orilẹ-ède na li emi o fi idà, ati ìyan, ati ajakalẹ-arun, jẹ niya, li Oluwa wi, titi emi o fi run wọn nipa ọwọ rẹ̀.

9. Nitorina ẹ máṣe fi eti si awọn woli nyin, tabi si awọn alafọṣẹ nyin, tabi si awọn alála, tabi si awọn oṣo nyin, tabi awọn ajẹ nyin ti nsọ fun nyin pe, Ẹnyin kì o sin ọba Babeli:

10. Nitori nwọn sọ-asọtẹlẹ eke fun nyin, lati mu nyin jina réré kuro ni ilẹ nyin, ki emi ki o lè lé nyin jade, ti ẹnyin o si ṣegbe.

Jer 27