1. BAYI li Oluwa wi, Sọkalẹ lọ si ile ọba Juda, ki o si sọ ọ̀rọ yi nibẹ.
2. Si wipe, Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ọba Juda, ti o joko ni itẹ Dafidi, iwọ, ati awọn iranṣẹ rẹ, ati awọn enia rẹ ti o wọle ẹnu-bode wọnyi.
3. Bayi li Oluwa wi; Mu idajọ ati ododo ṣẹ, ki o si gbà ẹniti a lọ lọwọ gbà kuro lọwọ aninilara, ki o máṣe fi agbara ati ìka lò alejo, alainibaba ati opó, bẹ̃ni ki o máṣe ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ silẹ nihinyi.
4. Nitori bi ẹnyin ba ṣe nkan yi nitõtọ, nigbana ni awọn ọba yio wọle ẹnu-bode ilu yi, ti nwọn o joko lori itẹ Dafidi, ti yio gun kẹ̀kẹ ati ẹṣin, on, ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati enia rẹ̀.