Jer 2:7-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Emi si mu nyin wá si ilẹ ọgba-eso, lati jẹ eso rẹ̀ ati ire rẹ̀; ṣugbọn ẹnyin wọ inu rẹ̀, ẹ si ba ilẹ mi jẹ, ẹ si sọ ogún mi di ohun irira:

8. Awọn alufa kò wipe, Nibo li Oluwa wà? ati awọn ti o mu ofin lọwọ kò mọ̀ mi: awọn oluṣọ si ṣẹ̀ si mi, ati awọn woli sọ asọtẹlẹ nipa Baali, nwọn si tẹle ohun ti kò lerè.

9. Nitorina, Emi o ba nyin jà, li Oluwa wi, Emi o si ba atọmọde-ọmọ nyin jà.

10. Njẹ, ẹ kọja lọ si erekuṣu awọn ara Kittimu, ki ẹ si wò, si ranṣẹ lọ si Kedari, ki ẹ si ṣe akiyesi gidigidi, ki ẹ wò bi iru nkan yi ba mbẹ nibẹ?

11. Orilẹ-ède kan ha pa ọlọrun rẹ̀ dà? sibẹ awọn wọnyi kì iṣe ọlọrun! ṣugbọn enia mi ti yi ogo wọn pada fun eyiti kò lerè.

12. Ki ẹnu ki o ya ọrun nitori eyi, ki o si dãmu, ki o si di gbigbẹ, li Oluwa wi!

13. Nitori awọn enia mi ṣe ibi meji: nwọn fi Emi, isun omi-ìye silẹ, nwọn si wà kanga omi fun ara wọn, kanga fifọ́ ti kò le da omi duro.

14. Ẹrú ni Israeli iṣe bi? tabi ẹru ibile? ẽṣe ti o fi di ijẹ.

15. Awọn ọmọ kiniun ke ramuramu lori rẹ̀, nwọn si bú, nwọn si sọ ilẹ rẹ̀ di ahoro, ilu rẹ̀ li a fi jona li aini olugbe.

16. Awọn ọmọ Nofi ati ti Tafanesi pẹlu ti jẹ agbari rẹ;

17. Fifi Oluwa ọlọrun rẹ silẹ kọ́ ha mu eyi ba ọ, nigbati o tọ́ ọ loju ọ̀na?

18. Njẹ nisisiyi kíni iwọ ni iṣe ni ipa-ọ̀na Egipti, lati mu omi Sihori? tabi kini iwọ ni iṣe ni ipa-ọ̀na Assiria lati mu omi odò rẹ̀.

Jer 2