29. Ẽṣe ti ẹnyin o ba mi jà? gbogbo nyin li o ti rufin mi, li Oluwa wi.
30. Lasan ni mo lù ọmọ nyin, nwọn kò gbà ibawi, idà ẹnyin tikara nyin li o pa awọn woli bi kiniun apanirun.
31. Iran enia yi, ẹ kiyesi ọ̀rọ Oluwa. Emi ha ti di aginju si Israeli bi? tabi ilẹ okunkun biribiri, ẽṣe ti enia mi wipe, awa nrin kakiri, awa kì yio tọ̀ ọ wá mọ.
32. Wundia le gbagbe ohun ọṣọ rẹ̀, tabi iyawo ọjá-ọṣọ rẹ̀? ṣugbọn enia mi ti gbagbe mi li ọjọ ti kò ni iye.
33. Ẽṣe ti iwọ tun ọ̀na rẹ ṣe lati wá ifẹ rẹ? nitorina iwọ ṣe kọ́ awọn obinrin buburu li ọ̀na rẹ.
34. Pẹlupẹlu ẹjẹ ẹmi awọn talaka ati alaiṣẹ mbẹ lara aṣọ rẹ, iwọ kò ri wọn nibi irunlẹ wọle, ṣugbọn lara gbogbo wọnyi.
35. Sibẹ iwọ wipe, alaiṣẹ̀ li emi, ibinu rẹ̀ yio sa yipada lọdọ mi. Sa wò o, emi o ba ọ jà, nitori iwọ wipe, emi kò ṣẹ̀.
36. Ẽṣe ti iwọ ṣe ati yi ọ̀na rẹ pada bẹ̃, oju yio tì ọ pẹlu fun Egipti, gẹgẹ bi oju ti tì ọ fun Assiria.
37. Lõtọ iwọ o kuro lọdọ rẹ̀, iwọ o si ka ọwọ le ori, nitori Oluwa ti kọ̀ awọn onigbẹkẹle rẹ, iwọ kì yio si ṣe rere ninu wọn.