Jer 2:13-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Nitori awọn enia mi ṣe ibi meji: nwọn fi Emi, isun omi-ìye silẹ, nwọn si wà kanga omi fun ara wọn, kanga fifọ́ ti kò le da omi duro.

14. Ẹrú ni Israeli iṣe bi? tabi ẹru ibile? ẽṣe ti o fi di ijẹ.

15. Awọn ọmọ kiniun ke ramuramu lori rẹ̀, nwọn si bú, nwọn si sọ ilẹ rẹ̀ di ahoro, ilu rẹ̀ li a fi jona li aini olugbe.

16. Awọn ọmọ Nofi ati ti Tafanesi pẹlu ti jẹ agbari rẹ;

17. Fifi Oluwa ọlọrun rẹ silẹ kọ́ ha mu eyi ba ọ, nigbati o tọ́ ọ loju ọ̀na?

18. Njẹ nisisiyi kíni iwọ ni iṣe ni ipa-ọ̀na Egipti, lati mu omi Sihori? tabi kini iwọ ni iṣe ni ipa-ọ̀na Assiria lati mu omi odò rẹ̀.

19. Ìwa-buburu rẹ ni yio kọ́ ọ, ipadasẹhin rẹ ni yio si ba ọ wi: mọ̀, ki iwọ si ri i pe, ohun buburu ati kikoro ni, pe, iwọ ti kò Oluwa Ọlọrun rẹ, ati pe ìbẹru mi kò si si niwaju rẹ; li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi.

20. Nitori ni igba atijọ iwọ ti ṣẹ́ ajaga ọrun rẹ, iwọ si já idè rẹ; iwọ si wipe, Emi kì o sìn, nitori lori oke giga gbogbo, ati labẹ igi tutu gbogbo ni iwọ nṣe panṣaga.

21. Ṣugbọn emi ti gbin ọ ni ajara ọlọla, irugbin rere patapata: ẽṣe ti iwọ fi yipada di ẹka ajara ajeji si mi?

22. Nitori iwọ iba wẹ ara rẹ ni ẽru, ki o si mu ọṣẹ pupọ, ẽri ni ẹ̀ṣẹ rẹ niwaju mi sibẹsibẹ, li Oluwa Ọlọrun wi.

23. Bawo li o ṣe wipe, emi kò ṣe alaimọ́, emi kò tọpa Baalimu? wò ọ̀na rẹ li afonifoji, mọ̀ ohun ti iwọ ti ṣe, iwọ dabi abo ibakasiẹ ayasẹ̀ ti nrin ọ̀na rẹ̀ ka.

24. Kẹtẹkẹtẹ igbẹ ti ima gbe aginju, ninu ifẹ ọkàn rẹ̀ ti nfa ẹfufu, li akoko rẹ̀, tani le yi i pada? gbogbo awọn ti nwá a kiri kì yio da ara wọn li agara, nwọn o ri i li oṣu rẹ̀.

Jer 2