Jer 18:4-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Ati ohun-èlo, ti o fi amọ mọ, si bajẹ lọwọ amọkoko na: nigbana ni o si mọ ohun-elo miran, bi o ti ri li oju amọkoko lati mọ ọ.

5. Ọrọ Oluwa si tọ̀ mi wá wipe,

6. Ẹnyin ile Israeli, emi kò ha le fi nyin ṣe gẹgẹ bi amọkoko yi ti ṣe, li Oluwa wi: sa wò o, gẹgẹ bi amọ̀ li ọwọ amọkoko, bẹ̃ni ẹnyin wà li ọwọ mi, ile Israeli.

7. Lojukanna ti emi sọ̀rọ si orilẹ-ède kan ati si ijọba kan lati fà a tu, ati lati fà a lulẹ, ati lati pa a run.

8. Bi orilẹ-ède na ti mo ti sọ ọ̀rọ si ba yipada kuro ninu ìwa-buburu rẹ̀, emi o yi ọkàn mi pada niti ibi ti emi ti rò lati ṣe si wọn.

9. Ati lojukanna ti emi sọ ọ̀rọ si orilẹ-ède kan ati si ijọba kan, lati tẹ̀ ẹ do ati lati gbìn i.

10. Bi o ba ṣe ibi niwaju mi, ti kò si gbà ohùn mi gbọ́: nigbana ni emi o yi ọkàn mi pada niti rere, eyiti mo wi pe, emi o ṣe fun wọn.

Jer 18