Nitorina, fi awọn ọmọ wọn fun ìyan, ki o si fi idà pa wọn, jẹ ki aya wọn ki o di alailọmọ ati opó: ki a si fi ìka pa awọn ọkunrin wọn, jẹ ki a fi idà pa awọn ọdọmọde wọn li ogun.