Jer 10:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ ti Oluwa sọ fun nyin, ẹnyin ile Israeli:

2. Bayi li Oluwa wi, Ẹ máṣe kọ́ ìwa awọn keferi, ki àmi ọrun ki o má si dãmu nyin, nitoripe, nwọn ndamu awọn orilẹ-ède.

3. Nitori asan ni ilana awọn orilẹ-ède; nitori igi ti a ke lati igbo ni iṣẹ ọwọ oniṣọna ati ti ãke.

4. Nwọn fi fádaka ati wura ṣe e lọṣọ, nwọn fi iṣo ati olù dì i mu, ki o má le mì.

5. Nwọn nàro bi igi ọpẹ, ṣugbọn nwọn kò fọhùn: gbigbe li a ngbe wọn, nitori nwọn kò le rin. Má bẹ̀ru wọn; nitori nwọn kò le ṣe buburu, bẹ̃li ati ṣe rere, kò si ninu wọn.

6. Kò si ẹnikan ti o dabi Iwọ Oluwa! iwọ tobi, orukọ rẹ si tobi ni agbara!

7. Tani kì ba bẹ̀ru rẹ, Iwọ Ọba orilẹ-ède? nitori tirẹ ni o jasi; kò si ninu awọn ọlọgbọ́n orilẹ-ède, ati gbogbo ijọba wọn, kò si ẹniti o dabi Iwọ!

Jer 10