3. Ẹnyin bère, ẹ kò si ri gbà, nitoriti ẹnyin ṣì i bère, ki ẹnyin ki o le lò o fun ifẹkufẹ ara nyin.
4. Ẹnyin panṣaga ọkunrin, ati panṣaga obinrin, ẹ kò mọ̀ pe ìbarẹ́ aiye ìṣọtá Ọlọrun ni? nitorina ẹnikẹni ti o ba fẹ lati jẹ́ ọrẹ aiye di ọtá Ọlọrun.
5. Ẹnyin ṣebi iwe-mimọ́ sọ lasan pe, Ẹmí ti o fi sinu wa njowu gidigidi lori wa?
6. Ṣugbọn o nfunni li ore-ọfẹ si i. Nitorina li o ṣe wipe, Ọlọrun kọ oju ija si awọn agberaga, ṣugbọn o fi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ ọkàn.
7. Nitorina ẹ tẹriba fun Ọlọrun. Ẹ kọ oju ija si Èṣu, on ó si sá kuro lọdọ nyin.
8. Ẹ sunmọ Ọlọrun, on o si sunmọ nyin, Ẹ wẹ̀ ọwọ́ nyin mọ́, ẹnyin ẹlẹṣẹ; ẹ si ṣe ọkàn nyin ni mimọ́, ẹnyin oniye meji.
9. Ki inu nyin ki o bajẹ, ki ẹ si gbàwẹ, ki ẹ si mã sọkun: ẹ jẹ ki ẹrín nyin ki o di àwẹ, ati ayọ̀ nyin ki o di ikãnu.
10. Ẹ rẹ̀ ara nyin silẹ niwaju Oluwa, on o si gbé nyin ga.
11. Ará, ẹ máṣe sọ̀rọ ibi si ara nyin. Ẹniti o ba nsọ̀rọ ibi si arakunrin rẹ̀, ti o si ndá arakunrin rẹ̀ lẹjọ, o nsọ̀rọ ibi si ofin, o si ndá ofin lẹjọ; ṣugbọn bi iwọ ba ndá ofin lẹjọ, iwọ kì iṣe oluṣe ofin, bikoṣe onidajọ.
12. Olofin ati onidajọ kanṣoṣo ni mbẹ, ani ẹniti ó le gbala ti o si le parun; ṣugbọn tani iwọ ti ndá ẹnikeji rẹ lẹjọ?
13. Ẹ wá nisisiyi, ẹnyin tí nwipe, Loni tabi lọla awa ó lọ si ilu bayi, a o si ṣe ọdún kan nibẹ, a o si ṣòwo, a o si jère:
14. Nigbati ẹnyin kò mọ̀ ohun ti yio hù lọla. Kili ẹmí nyin? Ikũku sá ni nyin, ti o hàn nigba diẹ, lẹhinna a si túka lọ.
15. Eyi ti ẹ bá fi wipe, bi Oluwa ba fẹ, awa o wà lãye, a o si ṣe eyi tabi eyini.
16. Ṣugbọn nisisiyi ẹnyin nṣeféfe ninu ifọnnu nyin: gbogbo irú iṣeféfe bẹ̃, ibi ni.
17. Nitorina ẹniti o ba mọ̀ rere iṣe ti kò si ṣe, ẹ̀ṣẹ ni fun u.