Jak 4:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIBO ni ogun ti wá, nibo ni ija si ti wá larin nyin? lati inu eyi ha kọ? lati inu ifẹkufẹ ara nyin, ti njagun ninu awọn ẹ̀ya-ara nyin?

2. Ẹnyin nfẹ, ẹ kò si ni: ẹnyin npa, ẹ si nṣe ilara, ẹ kò si le ni: ẹnyin njà, ẹnyin si njagun; ẹ ko ni, nitoriti ẹnyin kò bère.

3. Ẹnyin bère, ẹ kò si ri gbà, nitoriti ẹnyin ṣì i bère, ki ẹnyin ki o le lò o fun ifẹkufẹ ara nyin.

4. Ẹnyin panṣaga ọkunrin, ati panṣaga obinrin, ẹ kò mọ̀ pe ìbarẹ́ aiye ìṣọtá Ọlọrun ni? nitorina ẹnikẹni ti o ba fẹ lati jẹ́ ọrẹ aiye di ọtá Ọlọrun.

5. Ẹnyin ṣebi iwe-mimọ́ sọ lasan pe, Ẹmí ti o fi sinu wa njowu gidigidi lori wa?

6. Ṣugbọn o nfunni li ore-ọfẹ si i. Nitorina li o ṣe wipe, Ọlọrun kọ oju ija si awọn agberaga, ṣugbọn o fi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ ọkàn.

7. Nitorina ẹ tẹriba fun Ọlọrun. Ẹ kọ oju ija si Èṣu, on ó si sá kuro lọdọ nyin.

8. Ẹ sunmọ Ọlọrun, on o si sunmọ nyin, Ẹ wẹ̀ ọwọ́ nyin mọ́, ẹnyin ẹlẹṣẹ; ẹ si ṣe ọkàn nyin ni mimọ́, ẹnyin oniye meji.

9. Ki inu nyin ki o bajẹ, ki ẹ si gbàwẹ, ki ẹ si mã sọkun: ẹ jẹ ki ẹrín nyin ki o di àwẹ, ati ayọ̀ nyin ki o di ikãnu.

10. Ẹ rẹ̀ ara nyin silẹ niwaju Oluwa, on o si gbé nyin ga.

11. Ará, ẹ máṣe sọ̀rọ ibi si ara nyin. Ẹniti o ba nsọ̀rọ ibi si arakunrin rẹ̀, ti o si ndá arakunrin rẹ̀ lẹjọ, o nsọ̀rọ ibi si ofin, o si ndá ofin lẹjọ; ṣugbọn bi iwọ ba ndá ofin lẹjọ, iwọ kì iṣe oluṣe ofin, bikoṣe onidajọ.

Jak 4