5. Nitori Siria, Efraimu, ati ọmọ Remaliah ti gbìmọ ibi si ọ wipe.
6. Ẹ jẹ ki a gòke lọ si Juda, ki a si bà a ninu jẹ, ẹ si jẹ ki a ṣe ihò ninu rẹ̀ fun ara wa, ki a si gbe ọba kan kalẹ lãrin rẹ̀, ani ọmọ Tabeali:
7. Bayi ni Oluwa Jehofah wi, Ìmọ na kì yio duro, bẹ̃ni ki yio ṣẹ.
8. Nitori ori Siria ni Damasku, ori Damasku si ni Resini; ninu ọdun marunlelọgọta li a o fọ Efraimu ti ki yio si jẹ́ enia mọ.
9. Ori Efraimu si ni Samaria, ori Samaria si ni ọmọ Remaliah. Bi ẹnyin ki yio ba gbagbọ́, lotitọ, a ki yio fi idi nyin mulẹ.
10. Oluwa si tun sọ fun Ahasi pe,
11. Bere àmi kan lọwọ Oluwa Ọlọrun rẹ; bere rẹ̀, ibã jẹ ni ọgbun tabi li okè.
12. Ṣugbọn Ahasi wipe, Emi ki yio bere, bẹ̃ni emi ki yio dán Oluwa wò.